Àlá nípa Òjò

Àlá nípa òjò dá lórí bí òjò náà ṣe lágbára tó àti iye àkókò tó fi rọ̀. Òjò tó bá rọ̀ ní ìwọ̀ntunwọnsì lé túmọ̀ sí pé nǹkan ń bọ̀ – Ó lè jẹ́ ẹ̀bùn, ṣùgbọ́n ó tún lè jẹ́ nǹkan ibi bíi àìsàn. Ìjì nínú òjò náà le túmọ̀ sí wàhálà tàbí àìsàn ní ọjọ́ iwájú rẹ, o sì le bá ẹ̀tàn àti ìbànújẹ́ pàdé ní ayé rẹ. Àmọ́ṣá, tí o bá gbé ìgbésẹ̀ ọlọgbọ́n, o le kógojá ní ìkẹhìn. Tí o bá lálàá pé òjò náà dá, tí òòrùn sí yọ, ó le túmọ̀ sí oríire ní ọjọ́ iwájú rẹ.

Leave a Reply