Àlá nípa ìkọ̀sílẹ̀

Tí olólùfẹ́ rẹ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ojú àlá rẹ, ó lè túmọ̀ sí pé ẹni tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ lọ́wọ́ máa jẹ́ olóòótọ́ sí ẹ.

Alá nípa Adìyẹ

Tí o bá lálàá rí adìyẹ, ó lẹ́ jẹ́ àpẹẹrẹ ire fún ọ níwọ̀n ìgbà tí wọn o bá ti kó ọmọ lẹ́yìn. Láìsí ọmọ lẹ́yìn adìyé náà, àlá náà le túmọ̀ sí ìdùnnú àti oríire. Àmọ́, pẹ̀lú ọmọ adìyẹ, ó lẹ̀ túmọ̀ sí oríburúkú, ìkọ̀sílẹ̀, àti àdánù, àgàgà pẹ̀lú olólùfẹ́ tàbí lẹnu iṣẹ́

Àlá nípa Iṣẹ́ ọnà

Tí o ba lálàá pé ò ń ya àwòrán, ó lè túmọ̀ sí pé o máa di ayàwòrán ní ọjọ́ iwájú. Sùgbọ́n tí o bá rí i pé ò ń kun àwòrán ní ojú orun rẹ, èyí le jẹ́ àpẹẹrẹ ibi, nítorí ẹbi rẹ le bọ́ sí ipò àìní ní ọjọ́ iwájú.

Àlá nípa Ìbọn

Tí o bá lálàá rí ìbọn, ó lè tọ́ka sí wàhálà ní ìgbesí-ayé rẹ. Tí ó bá dún, ó ṣeéṣe kí àìsàn tàbí ìjà farahàn ní ayé rẹ láìpẹ́. Tí o bá jẹ́ pé ìwọ ní o yin ìbọn náà, èyí lè bùrú jàì.

Àlá nípa ẹyin

Tí o bá lálàá nípa ẹyin, ó lè túmọ̀ sí pé o má ṣe àṣeyọrí ní ẹnu iṣẹ́ tàbí ní ilé-ẹ̀kọ́. Amọ́ṣa, tí àwọn ẹyin náà bá ti bàjẹ́, ó le túmọ̀ sí pé ó ṣeéṣe kí o rí wàhálà ní ayé rẹ. Tí àwọn ẹyin náà bá dáa, o túmọ̀ sí pe o máa …

Funda okunye

Àlá nípa Ọtí bíà

Tí o bá lálàá pé ò ń po ọtí bíà, ó lè túmọ̀ sí pé o máa gbàlejò ẹnìkan láti ọ̀nà jínjìn. Tí o bá lálàá pé ò ń mu ọtí bíà ní ilé ọtí, èyí ń tọ́ka sí i pé o máa ní ọ̀tá ní àìpẹ́.

Àlá ní pa ayẹyẹ Ìgbéyàwó

Tí o bá lálàá pé o ń ṣe ìgbéyàwó, o le jẹ́ àpẹẹrẹ ibi, àgàgà ti o bá jẹ́ ọkùnrin. O lè túmọ̀ sí pé ìjàm̀bá ọkọ̀ tàbí ikú ń bọ̀ láyé rẹ láìpẹ́. Tí ó bá jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn èèyàn tí o rí lójú àlá rẹ ń ṣe àìsàn tàbí wọ́n jẹ́ …

Funda okunye

Àlá nípa ìjà

Tí o bá lálàá pé o na èèyàn lójú àlá rẹ,ó ṣeéṣe kí o rí ìdójútì ní ayé rẹ láìpẹ́, tàbí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí kò yọrí sí ire. Tí ó bá jẹ́ pé ẹnìkan ló ń nà ọ́ tí o sì ń dáàbòbò ara rẹ láì kọjú ìjà padà, o ṣeéṣe kí rí ìrírí ìdójútì láìpẹ́ …

Funda okunye

Àlá nípa Bàtà

Tí o ba lálàá nípa bàtà, ó lè jẹ́ àpẹẹrẹ pé o ṣe oríire, ìyẹn tí bàtà náà bá tuntun tí o sì ń dán, ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ bàtà tí ó ti gbó, ó lè túmọ̀ sí pé o máa kojú ìṣòro.