Tí o bá lálàá pé o na èèyàn lójú àlá rẹ,ó ṣeéṣe kí o rí ìdójútì ní ayé rẹ láìpẹ́, tàbí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí kò yọrí sí ire. Tí ó bá jẹ́ pé ẹnìkan ló ń nà ọ́ tí o sì ń dáàbòbò ara rẹ láì kọjú ìjà padà, o ṣeéṣe kí rí ìrírí ìdójútì láìpẹ́ torí ẹnìkan ń sọ̀rọ̀ rẹ lẹ́yìn.