Tí o bá lálàá pé o ń ṣe ìgbéyàwó, o le jẹ́ àpẹẹrẹ ibi, àgàgà ti o bá jẹ́ ọkùnrin. O lè túmọ̀ sí pé ìjàm̀bá ọkọ̀ tàbí ikú ń bọ̀ láyé rẹ láìpẹ́. Tí ó bá jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn èèyàn tí o rí lójú àlá rẹ ń ṣe àìsàn tàbí wọ́n jẹ́ aláàbọ̀-ara, ó lè jẹ́ ìgbéyàwó aláìládùn fún ọ. Ìgbà kan ṣoṣo tí ó lè túmọ̀ sí ire ni tí obìnrin bá lálàá pé ó ń ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú bàbá arúgbó.